Ìbáramu pẹ̀lú Fóònù Alágbèéká nínú PBS Àtẹ̀jáde 4.0

Kikọ nipasẹ

ninu

,

Ṣíṣe àtúnṣe ìbáramu fún fóònù alágbèéká lẹ́tọ̀ọ́ lè ṣòro gan-an, tí ẹnìkan bá sì ṣì í ṣe, àbájáde rẹ̀ máa ń burú jáì. Kódà, tí o kò bá tíì gbọ́, Google ti tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn ojúlé wẹ́ẹ̀bù tí kò bá fóònù alágbèéká mu ní oṣù Kẹrin ọdún 2015. Ní kúkúrú, ìbáramu fún fóònù alágbèéká jẹ́ ohun pàtàkì púpọ̀.

Nígbà Nàá Kí Ni Ìbáramu Fún Fóònù Alágbèéká?

A máa ń gbà pé ojúlé wẹ́ẹ̀bù kan báramu nígbà tí àwọn àkóónú rẹ̀ bá ní agbára láti bá oríṣiríṣi ìwọ̀n àti ìbú ojú ìbòjú mu nígbà tí a bá wò ó lórí àwọn ẹ̀rọ míràn yàtọ̀ sí kọ̀mpútà orí tábìlì. Ní ṣoki, tí o bá ti ṣe àgbéga sí PBS v4 tí o sì fẹ́ ṣe àgbékalẹ̀ tàbí kọ́ ojú-ewé kan, kò yẹ kí o ní ìṣòro kankan láti wò wọ́n, yálà lórí kọ̀mpútà orí tábìlì, fóònù alágbèéká tàbí tábílẹ́ẹ̀tì rẹ.

Ìbáramu nínú Àtẹ̀jáde 4.0

Nínú àmúgbégá tuntun wa, ẹgbẹ́ wa ti rí i dájú pé àbùdá wíwo fóònù alágbèéká tuntun ti PBS di ìrírí tí ó dán mọ́ran tí ó sì túbọ̀ báramu lápapọ̀: pẹ̀lú ọ̀rọ̀, àwòrán, àti gbogbo àwọn àkóónú míràn tí ń bá ìwọ̀n ìfihàn ojú ìbòjú ẹ̀rọ rẹ mu fúnra wọn.

Ní báyìí gbogbo àwọn àkọlé ló ń tún ara wọn ṣe fúnra wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ojú ìbòjú, kí o má bàa ní àwọn lẹ́tà títóbi jù nígbà tí o bá ń wo ojúlé tàbí ojú-ewé tí o kọ́ pẹ̀lú PBS lórí àwọn fóònù alágbèéká. Láti ṣàlàyé rẹ̀ dáadáa sí i:

Wíwo Ojúlé Rẹ Lórí Oríṣiríṣi Ìwọ̀n Ojú Ìbòjú

Láti tún rí i dájú pé ẹ̀yin ènìyàn mọ bí ojú-ewé yín ṣe rí lórí fóònù alágbèéká, a tún ti mú wíwo bí ó ṣe rí lórí fóònù láti orí kọ̀mpútà tábìlì ṣiṣẹ́. Nípa èyí, tí o bá fẹ́ yẹ ẹ́ wò bóyá ojú-ewé rẹ dára tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò pọndandan kí o la wàhálà yíyípadà láti orí fóònù (tàbí tábílẹ́ẹ̀tì) sí kọ̀mpútà tábìlì kọjá. Ní báyìí o lè yípadà sẹ́yìn àti sáwájú láàárín oríṣiríṣi ìwọ̀n ojú ìbòjú nígbàkúgbà nígbà tí o bá ń ṣe àgbékalẹ̀ ojú-ewé rẹ.

Pẹ̀lúpẹ̀lù, o tún lè ṣe àtúnṣe àlàfo àwọn ohun èlò rẹ ní pàtó fún àwọn tábílẹ́ẹ̀tì àti àwọn fóònù alágbèéká.

Nígbà náà kí ni èrò yín? Bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ àwọn àbùdá míràn wà tí a lè mú sunwọ̀n sí i nípa fóònù alágbèéká? Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ nínú abala àwọn ọ̀rọ̀ ìsọsọ ní ìsàlẹ̀!